Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni

Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni

Lati ọdọ Al-Baraa ọmọ 'Azib- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni", ìyẹn ni ọrọ rẹ pé: (Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (Ibrahim, Ayah 27).

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Wọn maa bi olugbagbọ leere ninu saare, awọn mọlaika meji ti a fi ṣe amojuto ìyẹn maa beere lọwọ rẹ nipa ìyẹn, awọn mejeeji ni Munkar ati Nakeer, gẹgẹ bi orúkọ awọn mejeeji ṣe wa ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn hadiisi, O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe eleyii ni ọrọ ti o fi ẹsẹ rinlẹ ti Ọlọhun sọ nipa rẹ pé: (Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (Ibrahim, Ayah 27).

فوائد الحديث

Dajudaju ibeere saare ododo ni.

Ọlọhun gbe ọla fun awọn ẹru Rẹ olugbagbọ ni aye ati ọrun pẹlu fifi ẹsẹ wọn rinlẹ lori ọrọ ti o rinlẹ.

Ọla ti o n bẹ fun ijẹrii imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ati kiku sori rẹ.

Ki Ọlọhun fi ẹsẹ olugbagbọ rinlẹ ni aye pẹlu ìdúróṣinṣin lori igbagbọ, ati titọ oju ọna taara, ati nigba iku pẹlu kiku lori imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo, ati ninu saare nigba ibeere awọn mọlaika mejeeji.

التصنيفات

Isẹmi inu sàréè