Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero

Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ohun ti ọmọniyan ba gba lero ni yoo maa jẹ tiẹ̀, ẹni tí hijra tiẹ̀ ba jẹ tori ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, hijra rẹ maa jẹ ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ẹni tí hijra rẹ ba jẹ torí ayé ti o fẹ ki ọwọ rẹ o tẹ̀ tabi torí obìnrin ti o fẹ́ fẹ́, hijra rẹ maa jẹ ohun ti o ba tori rẹ ṣe hijra ni”. Ninu gbólóhùn kan ti o jẹ ti Bukhaariy: “Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèrò anfaani kan pẹlu iṣẹ rẹ, anfaani yẹn naa ni o maa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ko si si ẹsan kankan fun un, ẹni tí ó bá wa gbèrò isunmọ Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, o maa gba ẹsan kódà ki o jẹ iṣẹ lásán bii jijẹ ati mimu. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fi àkàwé lélẹ̀ láti ṣàlàyé ilapa àníyàn nibi awọn iṣẹ pẹ̀lú didọgba wọn nibi àwòrán ti o hàn, o wa ṣàlàyé pe ẹni ti o ba gbèrò wíwá ìyọ́nú Ọlọhun pẹ̀lú hijra rẹ ati fifi ìlú rẹ sílẹ̀, hijra rẹ nǹkan ti o ba òfin mu ni ti a si maa tẹ́wọ́ gbà ti wọn si maa san an ni ẹsan lórí ẹ fun àníyàn òdodo rẹ, ẹni tí ó bá gbèrò anfaani ayé pẹ̀lú hijra rẹ, bii owó, tabi ipò, tabi òwò, tabi ìyàwó, anfaani yẹn ti o gbèrò naa ni o maa ri nibi hijra rẹ, ko si nii gba ẹsan.

فوائد الحديث

Isẹnilojukokoro lori imọkanga; tori pe Ọlọhun ko nii gba iṣẹ ayafi eyi ti wọn ba fi wa oju-rere Rẹ̀.

Awọn iṣẹ ti a fi maa n sunmọ Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ti ẹni tí o ti bàlágà ba ṣe e ni ti àṣà, ko nii gba ẹsan titi ti yoo fi gbero isunmọ Ọlọhun pẹlu ẹ.

التصنيفات

Awọn iṣẹ ọkan