“Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì

“Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì, àwọn ti wọn n ṣe deede nibi ìdájọ́ wọn, ati lọ́dọ̀ àwọn ará ilé wọn, ati nibi ohun ti n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe àwọn ti wọn n dajọ pẹ̀lú deede ati òdodo láàrin àwọn èèyàn ti wọn n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn ati idajọ wọn, ati ara ile wọn, wọ́n maa jókòó lori aga ti o ga ti wọn da latara imọlẹ, láti ṣe apọnle wọn ni ọjọ́ igbende. Ọwọ́ ọ̀tún Ọlọhun ni àwọn minbari yii maa wà, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ méjèèjì.

فوائد الحديث

Ọlá ti n bẹ fun deede ati ṣiṣenilojukokoro lori rẹ.

Deede kari gbogbo ìjọba ati idajọ láàrin àwọn èèyàn, titi dórí deede laarin awọn ìyàwó, ati awọn ọmọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣíṣe àlàyé ipò àwọn onideede ni ọjọ igbende.

Yiyatọ ipò àwọn onigbagbọ si ara wọn ni ọjọ́ igbende, onikaluku ni ibamu si iṣẹ rẹ ni.

Ọ̀nà ṣiṣenilojukokoro wa ninu awọn ọ̀nà ipepe ti maa n jẹ ki o wu ẹni tí a n pè lati tẹle ti Ọlọhun.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin