Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun

Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun

Lati ọdọ Amru ọmọ Shu'aib lati ọdọ baba rẹ lati ọdọ baba baba rẹ, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun".

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju o jẹ dandan lori baba lati pa awọn ọmọ rẹ láṣẹ- lọkunrin ati lobinrin- pẹlu irun ti awọn ọjọ ori wọn ba wa ni ọdun meje, ki o si kọ wọn ni nnkan ti wọn bukaata si lati gbe e duro. Ti wọn ba ti pe ọdun mẹwaa, o maa lekun ninu alamọri náà, o maa na wọn lori aṣeeto nibẹ, o si maa ya wọn nibi ibùsùn.

فوائد الحديث

Kikọ awọn ọmọ kekere ni awọn àlámọ̀rí ẹsin siwaju bibalaga, ninu eyi ti o ṣe pataki nibẹ ni irun.

Nina maa n jẹ nitori kikọ lẹkọọ, ko ki n ṣe tori ifiyajẹ, wọn maa na an ni nina ti o yẹ ẹ́.

Ikolekan Sharia si sisọ ọmọluwabi, ati kikọdi gbogbo ọna ti o le ja sibi ibajẹ.

التصنيفات

Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ