إعدادات العرض
“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”
“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”
Lati ọdọ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun mi pe: “Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.
[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە සිංහල ไทย دری Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių or Română Kinyarwanda Српски O‘zbek Moore नेपाली Oromoo Wolof Soomaali Malagasy Български Українська Azərbaycan ქართული bm тоҷикӣ Македонскиالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa, ki èèyàn si ma fi oju kéré rẹ kódà ki o kéré, ninu ìyẹn ni tituju ka pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ nígbà tí a ba pade. O tọ́ fun Mùsùlùmí ki o ṣe ojúkòkòrò rẹ; tori ifi ara ro ọmọ-ìyá ti o jẹ Mùsùlùmí wa ninu ẹ, ati mimu ìdùnnú wọ inu rẹ̀.فوائد الحديث
Ọla ti n bẹ fun ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, ati ẹ̀rín-músẹ́ ati ìtújúká ti wọn ba pade.
Pípé sharia ati kikari rẹ, ati pe o wa pẹlu gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun awọn Mùsùlùmí ati ṣíṣe wọn ní ọ̀kan.
Ṣiṣenilojukokoro lori ṣíṣe dáadáa kódà ki o kéré.
A fẹ ki a maa dun àwọn Musulumi ninu; tori pe ìyẹn maa jẹ ki ìfẹ́ o wa laarin wọn.
التصنيفات
Awọn iwa ẹyin