“Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”

“Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe saara kii din dúkìá ku, bi ko ṣe pe o maa n ti àwọn nǹkan ti o le ba a jẹ́ danu, Ọlọhun si maa n fi oore ńlá rọ́pò fun ẹni tí n ṣe saara, o maa wa jẹ alekun ni kii ṣe adinku. Amojukuro pẹlu ikapa lati gba ẹsan kii le ẹni ti o ba ṣe e kun nǹkan kan ayafi ni agbara. Ẹnikan ko nii tẹrí ba tori ti Ọlọhun, ti kii ṣe ti ibẹru ẹnikẹ́ni, tabi ti ẹ̀tàn, tabi wiwa anfaani kan lọ́dọ̀ rẹ, àyàfi ki ẹsan rẹ o jẹ gíga ati iyì.

فوائد الحديث

Oore n bẹ nibi ṣíṣe amulo sharia ati ṣíṣe dáadáa kódà ki awọn èèyàn kan maa lérò idakeji rẹ.

التصنيفات

Saara aṣegbọrẹ, Saara aṣegbọrẹ