إعدادات العرض
Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ
Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ
Lati ọdọ Jeriir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: A wa lọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa wo òṣùpá ni alẹ ọjọ́ kan- o n túmọ̀ si òṣùpá ọjọ kẹrinla- o wa sọ pe: "Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ, ti ẹ ba ni ikapa ki wọn maa kọdi yin kuro nibi irun ṣíwájú yiyọ oorun ati ṣíwájú wiwọ rẹ, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ" lẹyin naa o ka:"(Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).)"
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Türkçe اردو 中文 हिन्दी বাংলা Kurdî Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் සිංහල မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Hausa دری Кыргызча or Kinyarwanda नेपाली Malagasy Română Lietuvių Oromoo Српски Nederlands Soomaali Українська ಕನ್ನಡ Wolof Moore ქართული Azərbaycan Magyar Tagalogالشرح
Awọn saabe wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni alẹ ọjọ kan, o wa wo òṣùpá- ni ale ọjọ kẹrinla-, o wa sọ pe: Dajudaju awọn olugbagbọ maa ri Oluwa wọn ni ti paapaa pẹlu oju laisi iruju, ati pe wọn ko nii fún papọ mọ́ra wọn, wahala tabi inira ko nii ṣẹlẹ̀ si wọn nibi riri Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga-. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ti ẹ ba ni ikapa lati ge awọn okunfa ti o le yi yin kuro nibi irun asunbaa ati irun Asr, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ, ki ẹ si mu mejeeji wa ni pipe ni asiko mejeeji ni janmọọn, dajudaju ìyẹn wa ninu awọn okunfa wiwo oju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka aaya naa: (Wa sabbih bihamdi Robbika qobla tuluu'ish shamsi wa qoblal guruub)فوائد الحديث
Iro idunnu fun oni igbagbọ pẹlu riri Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ninu alujanna.
Ninu awọn ọna ipepe ni: Ikanpamọ ati ifanilojumọra ati mimu awọn apẹẹrẹ wa.
التصنيفات
Isẹmi ọjọ ìkẹyìn