ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan

ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, Ibnu Jud’aan maa n da ibi pọ ni asiko ki Isilaamu to de, o si maa n fun awọn alaini ni oúnjẹ, njẹ ìyẹn maa ṣe e ni anfaani? O sọ pe: “Ko lee ṣe e ni anfaani, nitori pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa Abdullahi Bn Jud’aan, o si wa ninu awọn aṣiwaju Kuraiṣi ṣíwájú Isilaamu, Ninu awọn iṣẹ daadaa rẹ ni pé: O maa n da awọn ẹbi pọ, o si maa n ṣe daadaa si wọn, o si maa n fun alaini ni oúnjẹ, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ọlọla ti Isilaamu ṣe wa lojukokoro lori ṣíṣe wọn, ati pe awọn iṣẹ yii ko lee ṣe e ni anfaani ni ọjọ igbedide rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun okunfa ṣíṣe aigbagbọ rẹ ninu Ọlọhun, ati pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, forí awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan.

فوائد الحديث

Alaye ọla ti o n bẹ fun nini igbagbọ, ati pe o jẹ majẹmu fun gbigba awọn iṣẹ.

Alaye apẹrẹ buruku aigbagbọ, ati pe o wa ninu awọn nnkan ti o n ba awọn iṣẹ oloore jẹ.

Àwọn alaigbagbọ, awọn iṣẹ wọn ko nii ṣe wọn ni anfaani ni ọjọ igbedide nitori aigbagbọ wọn ninu Ọlọhun ati ọjọ igbedide.

Àwọn iṣẹ́ ọmọniyan ni ipo aigbagbọ rẹ, wọn maa kọ wọn fun un ti o ba gba Isilaamu, wọn yoo si san an ni ẹsan lori wọn.

التصنيفات

Ẹsin Isilaamu, Aigbagbọ