“Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”

“Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”.

[O ni alaafia] [Al-Haakim ati At-Tọbarọọniy ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ maa n gbo ni ọkan Musulumi o si maa n lẹ gẹgẹ bi aṣọ tuntun ti o maa n gbo ti wọn ba ti lo o fun ìgbà pípẹ́; Ati pe ìyẹn maa n ṣẹlẹ̀ pẹlu okunfa adinku nibi ijọsin, tabi dida awọn ẹṣẹ ati titẹri sinu awọn adun. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ́ wa sọna lati maa pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati maa sọ igbagbọ wa di tuntun, pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan ati pipọ ni iranti ati wiwa aforijin.

فوائد الحديث

Ṣíṣenilojukokoro lori bibeere ìdúróṣinṣin ati sisọ igbagbọ di tuntun ninu ọkan lọdọ Ọlọhun.

Igbagbọ jẹ ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan, o maa n lekun pẹlu itẹle, ó si maa n dinku pẹlu ẹṣẹ.

التصنيفات

Lilekun igbagbọ ati adinku rẹ