إعدادات العرض
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ
Láti ọ̀dọ̀ Ziyaad ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ”, mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni imọ ṣe máa lọ ti a si n ka Kuraani, ti a si n mu awọn ọmọ wa ka a, ti àwọn ọmọ wa naa si n mu awọn ọmọ wọn ka a titi di ọjọ igbende? O sọ pe: “Ó ṣe fún ẹ, irẹ Ziyaad, ti mo si n lérò pé ó wa ninu awọn ti wọn ni agbọye ẹsin ju ninu ilu Mẹdina, ṣe àwọn Júù ati awọn Kristẹni o maa ka Taoreeta ati Injiila ni, ti wọn kò sì ṣiṣẹ pẹlu nǹkan kan ninu nǹkan ti o wa nínú méjèèjì?!”.
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Español Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe Bosanski සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa മലയാളം తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া Shqip دری Ελληνικά Български Fulfulde Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek नेपाली Moore Kurdî Wolof Soomaali Français Oromoo Azərbaycan Tagalog Українська mr தமிழ் bm Deutsch ქართული Português mk Magyarالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jókòó laarin awọn saabe rẹ, o wa sọ pé: Eyi ni àsìkò ti wọn maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, Ziyaad ọmọ Labiid Al-Ansọọriy wá ṣe eemọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o wa beere lọwọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa sọ pé: Báwo ni wọ́n ṣe maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ wa?! Ti a si ti ka Kuraani ti a si ha a; mo fi Ọlọhun búra, a o maa ka a, a si maa jẹ ki awọn ìyàwó ati awọn ọmọ wa ka a, ati awọn ọmọ-ọmọ wa, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ẹni tí n ṣe eemọ pé: O ṣe fun ẹ, irẹ Ziyaad! Tí mo si n ka ọ kun ara àwọn onimimọ nínú àwọn ará ilu Mẹdina! Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé fun un pé: Pipadanu imọ kii ṣe pẹ̀lú pipadanu Kuraani; ṣùgbọ́n pipadanu imọ ni ki èèyàn má lò ó, Taoreeta ati Injiila n bẹ lọdọ awọn Juu ati awọn Kristẹni, tòun ti bẹ́ẹ̀ ko ṣe wọn ni anfaani, wọn ko si ṣe àǹfààní latara erongba àwọn méjèèjì; òun naa ni ki wọn lo ohun ti wọn mọ̀.فوائد الحديث
Bibẹ Kuraani ati awọn tira ni iwájú àwọn èèyàn ko lee ṣe àǹfààní lai fi ṣe iṣẹ́ ṣe.
Kíká imọ kúrò nilẹ maa wáyé pẹ̀lú àwọn àlámọ̀rí kan, nínú wọn ni: Ikú Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ati ikú àwọn onimimọ, ati ki èèyàn má lo imọ naa.
Ninu awọn àmì ti ayé ba fẹ parẹ ni lílọ imọ ati ki èèyàn má lò ó.
Ṣisẹnilojukokoro lórí lílo imọ; torí pé oun gan ni nǹkan ti a gbà lérò.