“Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn

“Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn

Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn, ẹ si ma ṣẹsa lati wa ni iwájú ni àwọn àpéjọ pẹ̀lú ẹ, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn, iná ni, iná ni”.

[O ni alaafia] [Ibnu Maajah ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kilọ kúrò nibi wiwa imọ lati maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, ati lati le fi hàn pé onimimọ bii tiyín ni èmi náà, tabi lati fi ba àwọn omugọ ati awọn ti làákàyè wọn lẹ sọ̀rọ̀ lati ba wọn jiyàn, tabi ki o kọ imọ lati wa ni iwájú ni àpéjọ, ti wọn si maa ti i saaju ẹlòmíràn nibẹ. Ẹni tí ó bá ṣe iyẹn; o ni ẹtọ si iná pẹlu ṣekarimi rẹ ati àìní imọkanga nibi wiwa imọ naa nítorí Ọlọhun.

فوائد الحديث

Àdéhùn ìyà iná fun ẹni ti o ba kọ imọ lati maa ṣe iyanran pẹ̀lú ẹ, tabi ìjiyàn pẹ̀lú ẹ, tabi wiwa ni iwájú nibi àpéjọ pẹ̀lú ẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Pataki mimọ àníyàn kangá fun ẹni ti o ba kọ́ imọ ti o si tun kọ ẹlòmíràn.

Aniyan ni ipilẹ àwọn iṣẹ, ori rẹ naa si ni ẹsan maa wa.

التصنيفات

Awọn aisan ọkan, Aleebu ifẹ inu ati awọn adun aye, Merit and Significance of Knowledge