Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?

Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?

Lati ọdọ Qataadah- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fún wa pe arákùnrin kan sọ pé: Irẹ Anọbi Ọlọhun, bawo ni wọn ṣe maa gbé keferi dìde lori ojú rẹ? O sọ pe: “Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?”, Qataadah sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi agbára Olúwa wa búra.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Wọn bi Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pe: Báwo ni wọn ṣe maa gbe Kèfèrí dìde lori ojú rẹ ni Ọjọ́ Àjíǹde?! Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ǹjẹ́ Olọhun tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?! Ọlọhun ni ikapa lori gbogbo nǹkan.

فوائد الحديث

Iyẹpẹrẹ Kèfèrí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ati pe o maa fi ojú rẹ rìn ni ọjọ naa.

التصنيفات

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin., Taohiid ti rubuubiyyah, Taohiid ti àwọn orúkọ ati awọn iroyin