“Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”

“Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”

Lati ọdọ Abu Huraira, lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn eniyan kan maa han ni igbẹyin ìjọ rẹ ti wọn maa maa da adapa-irọ, ti wọn maa maa sọ nnkan ti ẹnikẹni ko sọ ṣíwájú wọn, ti wọn maa maa sọrọ pẹlu awọn hadiisi irọ ati agbelẹrọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pa wa láṣẹ lati jina si wọn ki a si ma jokoo pẹlu wọn, ki a si ma tẹti si awọn hadiisi wọn; ki hadiisi ti wọn hun yii ma baa duro ninu awọn ẹ̀mí, ki a ma baa kagara kuro nibi lila kuro nibẹ.

فوائد الحديث

Ami kan n bẹ nibẹ ninu awọn ami ijẹ anabi, nigba ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ si ijọ rẹ, o si ri gẹgẹ bi o ṣe sọ.

Jijina si ẹni ti o ba n parọ mọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati nipa ẹsin Isilaamu, ati lati ma tẹti si irọ wọn.

Kikilọ kuro nibi gbigba awọn hadiisi wọle tabi fifọn wọn ka afi lẹyin riri amọdaju nipa nini alaafia wọn tabi ifi-ẹsẹ-rinlẹ wọn.

التصنيفات

Pàtàkì sunna ati ipò rẹ, Kikọ sunna Anọbi silẹ, Isẹmi inu sàréè