Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe

Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe

Lati ọdọ Warrood olukọwe Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah, o sọ pe: Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah pe àpèkọ fun mi ninu iwe kan si Mu’aawiyah pe: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘atoita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘ah'toita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”. O n túmọ̀ si pe: Mo n fi rinlẹ mo si n gba gbolohun imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo “Laa ilaaha illallohu” wọlé, ati pe ijọsin ododo mo n fi i rinlẹ fun Ọlọhun, mo si n kọ ọ fun ẹni ti o yatọ si i, ati pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, mo si n fi ọla gangan ti o pe rinlẹ fun Ọlọhun, ati gbogbo ọpẹ awọn ara inu sanmọ ati ilẹ jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nigba ti O ṣe pe Onikapa ni lori gbogbo nnkan, ati pe nnkan ti Ọlọhun ba kadara rẹ ninu fifun ati kikọ, ko si oludapada kankan fun un, lọdọ Rẹ, ọrọ ko lee ṣe ọlọrọ ni anfaani, bi ko ṣe pe iṣẹ rere ni yoo ṣe e ni anfaani.

فوائد الحديث

Ṣíṣe iranti yii ni nnkan ti a fẹ lẹyin awọn irun fun nnkan ti o ko sinu ninu awọn gbolohun imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo ati ọpẹ.

Yiyara si ṣíṣe àwọn sunnah, ati fifọn wọn ka.

التصنيفات

Awọn iranti irun