إعدادات العرض
Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun
Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Umar ọmọ Khatob fun mi niroo pe: Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt Kurdî Português සිංහල Svenska ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Hausa Kiswahili پښتو অসমীয়া دری Malagasy or Čeština नेपाली Oromoo Română Nederlands Soomaali తెలుగు Српски ไทย മലയാളം Kinyarwanda Кыргызча ಕನ್ನಡالشرح
Umar - ki Ọlọhun yọnu si i - funni niroo pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ri arakunrin kan ti o ti pari aluwala rẹ, ti o wa fi deedee eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ ti ko mu omi aluwala de ibẹ, Ni o wa sọ lẹni ti o na'ka si aaye aṣeeto yẹn: Pada ki o lọ ṣe aluwala rẹ daadaa ki o si pe e ki o si tun fun oríkèé kọọkan ni ẹtọ rẹ ninu omi, Ni arakunrin naa ba pada ti o sì lọ pe aluwala rẹ lẹyin naa ni o kirun.فوائد الحديث
Jijẹ dandan yiyara lati pàṣẹ daadaa, ati titọ alaimọkan ati onigbagbe sọnà, pataki julọ ti bibajẹ ijọsin ba maa jẹ yọ latara aidara yẹn.
Jijẹ dandan fifi omi kari gbogbo ara, ati pe ẹni ti o ba fi ipin (aaye) kan ninu oríkèé ara silẹ - koda ki o ma to nkankan - aluwala rẹ o ni alaafia o si tun jẹ dandan fun un ki o tun un ṣe tí alaafo yẹn ba ti gun.
Ṣiṣe imaa ṣe aluwala daadaa ni ofin, ati pe iyẹn ni pipe e ati ṣiṣe e daadaa lori ojupọna ti ofin fi pàṣẹ rẹ.
Ẹsẹ mejeeji ninu awọn oríkèé aluwala ni wọ́n wa, pipa mejeeji o si lẹẹ tọ, bí kò ṣe pe ko si ibuyẹ kuro nibi fifọ (ẹsẹ mejeeji).
Yiyara ṣe awọn oríkèé aluwala tẹle ara wọn jẹ nkan to lẹẹ tọ, ni èyí ti o ṣe pe yio fọ oríkèé kọọkan ṣíwájú ki èyí tí o ṣaaju rẹ o to gbẹ.
Aimọkan ati igbagbe wọn o lee bi ọranyan wo, nkan ti wọn le mu kuro ni ẹṣẹ, nitori naa arakunrin ti ko ṣe aluwala rẹ daadaa latara aimọkan rẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o bi ọranyan wo fun un, oun naa ni aluwala, o tun pa a l'aṣẹ ki o tun un ṣe ni.
التصنيفات
Awọn origun aluwala