إعدادات العرض
Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ
Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o sọ pe: Dajudaju Ummu Habeebah ọmọ Jahsh ti o wa labẹ 'Abdur Rahman ọmọ 'Aof, o gbe ẹjọ́ ẹjẹ lọ sọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ fun un pé: "Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ". O si jẹ ẹni ti maa n wẹ nibi gbogbo irun.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Hausa Kurdî Português සිංහල Svenska ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Tiếng Việt Kiswahili پښتو অসমীয়া دری Malagasy or Čeština नेपाली Oromoo Română Nederlands Soomaali Кыргызча తెలుగు ไทย Српски മലയാളം Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Lietuviųالشرح
Ẹnikan ninu awọn saabe lobinrin fi ẹjọ àìdá ẹjẹ rẹ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa pa a láṣẹ kí ó má kirun ni odiwọn igba ti ẹjẹ nnkan oṣu rẹ fi maa n dè é mọle ṣíwájú ki àlámọ̀rí pajawiri yii o to ṣẹlẹ̀ si i, lẹyin naa o maa wẹ, o si maa kirun, o si jẹ ẹni ti maa n fínnú-fíndọ̀ wẹ fun gbogbo irun kọọkan.فوائد الحديث
Istihaadoh (Ẹjẹ awaada) ni: Ki jijade ẹjẹ maa tẹsiwaju lẹyin awọn ọjọ nnkan oṣu rẹ ti a ba saaba.
Ẹni ti ẹjẹ awaada ń da lara rẹ yio ka ara rẹ si ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ni odiwọn awọn ọjọ ti nnkan oṣu fi maa n wa ba a nibẹ, ṣíwájú ki nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si i to ṣẹlẹ̀ si i ninu ẹjẹ awaada.
Ti odiwọn awọn ọjọ nnkan oṣu rẹ ipilẹ ba ti lọ, wọn maa ka a si ẹni ti o mọra kuro nibi nnkan oṣu- koda ki ẹjẹ awaada wà pẹlu rẹ- yio wẹ kuro ninu nnkan oṣù.
Ẹni ti ẹjẹ awaada maa n da lara rẹ, ko jẹ dandan fun un lati maa wẹ fun gbogbo irun kọọkan; nitori pe iwẹ rẹ- ki Ọlọhun yọnu si i- igbiyanju imọ agbọye ẹsin lati ọdọ rẹ ni, ti o ba jẹ dandan ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- koba ṣe alaye fun un.
Ẹni ti ẹjẹ awaada maa n da lara rẹ, ṣíṣe aluwala fun gbogbo irun kọọkan jẹ dandan fun un; nitori pe ẹgbin rẹ jẹ nnkan ti o n lọ tí kò dá, iru rẹ ni gbogbo ẹni ti ẹgbin rẹ ba n lọ gẹgẹ bi ẹni ti o ni itọ tí kò dá, tabi iso ti o n jade léraléra.
Bibeere nnkan ti o ruju ninu awọn àlámọ̀rí ẹsin lọdọ awọn onimimọ, nigba ti obinrin yii fi ẹjọ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti o si bi i leere nipa apọju ẹjẹ ti o n ṣẹlẹ̀ si i.
التصنيفات
Nnkan oṣu ati nifas ati ẹjẹ awaada