?Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara

?Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara

Lati ọdọ Abu Marthad Al-ganawiy – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ kuro nibi jijokoo si ori awọn sàréè. Gẹgẹ bi o ṣe kọ kuro nibi kiki irun si awọn sàréè, bii ki sàréè o wa ni agbegbe idojukọ olukirun; nitori pe dajudaju ìyẹn wa ninu awọn atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.

فوائد الحديث

Kikọ kuro nibi kiki irun ni itẹ tabi ni aarin rẹ tabi si i lára ayaafi irun oku gẹgẹ bi o ṣe fi ẹsẹ mulẹ ninu sunnah.

Kikọ kuro nibi kiki irun si sàréè lati dena ijẹ-atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.

Isilaamu kọ kuro nibi ikọja ààlà nibi awọn sàréè ati kuro nibi yiyẹpẹrẹ rẹ, ko gbọdọ si àṣejù ko si gbọdọ si aseeto.

Ọwọ Musulumi si ṣẹku lẹyin iku rẹ, latari gbolohun rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti o sọ pe: (Rirun eegun oku da gẹgẹ bii rirun un (eegun) ni ààyè ni).

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah, Taohiid ti uluuhiyyah, Awọn majẹmu irun, Awọn majẹmu irun