Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj

Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ fun arabinrin kan ninu awọn Ansaar, Ibnu Abbās darukọ rẹ, mo wa gbagbe orukọ rẹ, o sọ fun un pe: «Kini o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa?» O sọ pe: A ko ni ju rakunmi meji lọ (ti a fi maa n fun oko wa lomi) ti ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ si ṣe irinajo hajj lori ẹyọkan, o si fi ẹyọkan silẹ fun wa lati maa lo o lati fi maa pọn omi, o sọ pe: «Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Nígbà tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹri lati hajj idagbere, o sọ fún arabinrin kan ninu Ansaar ti ko ṣe hajj pe: Kini nkan ti o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa? O wa mu awijare wa pe awọn ni rakunmi meji, ti ọkọ oun ati ọmọ òun si ṣe hajj lori ọkan ninu mejeeji, ti o si fi ẹyọkan silẹ lati lẹ maa fi i pọn omi lati inu kanga. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fun un ni iro pe dajudaju ṣiṣe umurah ninu oṣu ramadan ẹsan rẹ ṣe deedee ẹsan hajj.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ nibi umura ninu oṣù Ramadan.

Umurah inu Ramadan ṣe deedee hajj nibi ẹsan, kìí ṣe nibi titi ijẹ ọranyan hajj ṣubu.

Ẹsan awọn iṣẹ maa n lekun pẹlu alekun iyi awọn asiko, ninu iyẹn naa ni awọn iṣẹ inu Ramadan.

التصنيفات

‏Ọla ti n bẹ fun hajj ati Umrah