Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl

Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n ṣe adua ti o si maa n sọ pe: «Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl». Nibi ti gbolohun ti Muslim: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti pari ataaya igbẹyin, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn nkan mẹẹrin: Nibi iya jahannamọ, ati nibi iya saare, ati nini fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi aburu al-Masiihu ad-Dajjāl».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi nkan mẹẹrin, lẹyin ataaya igbẹyin ati siwaju salamọ ninu irun, o si tun pa wa laṣẹ ki a maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibẹ, Ikinni: Nibi iya saare. Ẹẹkeji: Nibi iya ina ati pe ìyẹn ni ọjọ igbedide. Ẹẹkẹta: Nibi fitina iṣẹmi bi awọn adun aye ti o jẹ eewọ ati awọn iruju ti maa n sọni nu, ati nibi fitina iku, ìyẹn ni àsìkò pipọka iku, bii yiyẹ kuro ninu Isilaamu tabi Sunnah, tabi fitina saare gẹgẹ bii ibeere awọn malaika mejeeji. Ẹẹkẹrin: Fitina al-Masiihu ad-Dajjāl eleyii ti yio jade ni igbẹyin aye, Ọlọhun yio fi i dan awọn ẹru Rẹ wo; o wa darukọ rẹ lọ́tọ̀ latari titobi fitina rẹ ati isọninu rẹ.

فوائد الحديث

Iwa iṣọra yii ninu awọn adua ti o pataki ti o si kun fọfọ ni, latari pe o ko iwa iṣọra kuro nibi awọn aburu aye ati alukiyaamọ sinu.

Ririnlẹ iya saare ati pe dajudaju ododo ni i.

Ewu awọn fitina ati pataki wiwa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun ati ṣiṣe adua fun lila kuro ninu rẹ (fitina).

Fifi jijade dajjāl ati titobi fitina rẹ rinlẹ.

Ṣiṣe adua yii ni sunnah lẹyin ataaya igbẹyin.

Ṣiṣe adua ṣiṣe ni sunnah lẹyin iṣẹ oloore.

التصنيفات

Awọn iranti irun