?Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun

?Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun

Lati ọdọ Thaobān - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun» Abu Qilābah wa sọ pe: O bẹrẹ pẹlu ara ilé, lẹyin naa ni Abu Qilābah wa sọ pe: Ẹni wo ni ẹsan rẹ fi wa n tobi ju ẹni ti o n na owo lori awọn ọmọ rẹ kéékèèké, ti ko nii jẹ ki wọn maa tọrọ jẹ, tabi ti Ọlọhun o fi i ṣe wọn ni anfaani ti yio si tun rọ wọn lọrọ.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye oríṣiríṣi ọ̀nà téèyàn lè gbà náwó, ti o si tun to o ti awọn ọna inawo ba fún pọ̀ ni ibamu si bi wọn ṣe jẹ dandan le ọ l'ori si, ni o wa bẹrẹ pẹlu eyiti o pataki julọ lẹyin naa eyiti o pataki tẹle e. Ni o wa sọ pe dajudaju owo ti ẹsan rẹ pọ ju ni eyi ti musulumi na lori awọn ti inawo wọn jẹ dandan fun un; bii iyawo ati ọmọ, Lẹyin naa ni inawo lori nkan ọ̀gùn ti wọn pese kalẹ fun ijagun si oju-ọna Ọlọhun, Lẹyin naa ni inawo lori awọn ọrẹ ati alabaarin ni igba ti wọn n jagun si oju-ọna Ọlọhun.

فوائد الحديث

Tito inawo tẹle ara wọn nibi ọla ni ọna ti a sọ yẹn, èèyàn si maa ṣe àkíyèsí rẹ nígbà tí wọn ba funpọ.

Ṣiṣe alaye pipataki inawo lori ara ilé nibi nini ọla ju ẹlòmíràn lọ.

Inawo s'ibi jijagun si oju-ọna Ọlọhun ninu awọn inawo ti o tobi julọ ni, gẹgẹ bii pipese awọn nkan èlò ati awọn eeyan fun ogun.

Wọn sọ pe: Nkan ti wọn gba lero pẹlu oju-ọna Ọlọhun ni gbogbo itẹle aṣẹ gẹgẹ bii hajj fún àpẹrẹ.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ rere, Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ awọn orikerike ara