“Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run

“Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run” Wọ́n sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, kí ni awọn nkan naa? Ó ní: “Ṣíṣe ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, pípidán, pípa eniyan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ, àyàfi pẹlu ẹ̀tọ́, jíjẹ owó èlé, jíjẹ owó ọmọ òrukàn, sísálọ ní ọjọ́ ogun ẹsin, ati jíju òkò ṣina mọ́ awọn obinrin abilékọ, onígbàgbọ́ ododo, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n paṣẹ fún àwọn ijọ rẹ̀ pé kí wọ́n jinna sí awọn iwa ọdaran ati ẹṣẹ meje ti n pani run, nigba ti wọ́n wá bi i leere pé kí ni wọ́n? O ṣalaye pé àwọn ni: Ikinni: Ṣíṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun, nipasẹ wíwá alafiwe ati alafijọ fun Un, èyí ó wù ki o jẹ, mimọ ni fún Ọlọhun, ati ṣiṣe eyikeyii ninu awọn ijọsin fún ẹlomiran tó yatọ si Ọlọhun Allah, Ọba Aleke ọla. Àti pé Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – bẹrẹ pẹlu ẹbọ; nitori pe oun ló tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ. Ikeji: Idán ṣíṣe – oun naa ni títa kókó àwọn nkankan, ati pípọfọ̀, ati awọn oogùn, ati awọn èéfín ti n rú jáde – yoo lapa lára ẹni tí wọ́n bá ṣe idan sí, bii kí o pa ẹni naa, tabi kí ó kó àisàn ba a, tabi kí ó fa ipinya laarin ọkọ ati aya. Iṣẹ ẹ̀ṣù ni, ati pé wọn ò lè rí ọpọlọpọ ninu awọn idan yi ṣe ayafi nipasẹ ẹbọ ati ìpèsè nkan ti awọn ẹ̀mí eṣu buruku nífẹ̀ẹ́ si fun wọn. Ẹkẹta: Pípa ẹmi ti Ọlọhun ṣe ni eewọ lati pa a ayafi pẹ̀lú nǹkan ti o maa sọ ọ́ di ẹ̀tọ́ ti o ba ṣẹria mu ti oludajọ ṣẹria sì maa mu u ṣẹ. Ẹkẹrin: Gbígba owo èlé lati lè jẹ́ ẹ tabi lilo o ní ọna miiran ninu awọn ọna anfaani. Ìkarùn-ún: Ìtayọ àlà sí owó ọmọ kékeré tí bàbá rẹ̀ kú nígbà tí kò ì tíì bàlágà. Ẹkẹfa: Sísá kúrò loju ogun ẹsin pẹ̀lú awọn keferi. Ìkeje: Fífi ẹ̀sùn àgbèrè kan àwọn obìnrin olómìnira, oluṣọra nibi ìranù, àti fífi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin bakan naa.

فوائد الحديث

Awọn ẹṣẹ ńláǹlà kò pin sí ori meje, ati pé dídá awọn meje wọnyi ṣà lẹṣa jẹ́ nitori titobi wọn ati ewu wọn.

O tọ́ lati pa ẹmi kan tí ó bá jẹ́ pẹlu ẹ̀tọ́, gẹgẹ bii gbigbẹsan ati kíkómọ̀ ati àgbèrè lẹhin igbeyawo, ati pé oludajọ sharia ló ma ṣe e.

التصنيفات

Awọn iwa eebu, Aleebu awọn ẹṣẹ