Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀

Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n fun wa ni iro pe: Ọlọhun, Onibukun ti O ga julọ sọ pe: Òun ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún, Òun ni Ẹni tí Ó rọrọ̀ tayọ gbogbo nkan, ati pe ti eniyan bá ṣe iṣẹ ijọsin kan, ti o sì ṣe e fun Ọlọhun ati ohun miiran tó yatọ si Ọlọhun; Ọlọ́hun yoo gbe e ju sílẹ̀, kò nii gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, yoo sì dá a padà fún un. Nitori naa, ọranyan ni ki iṣẹ́ jẹ́ mimọ fun Ọlọ́hun Ọba Aleke ọla, nítorí pé, Ọlọ́hun – mimọ fun Un – kò nii gba iṣẹ kan ayafi eyiti ó jẹ́ mimọ lati lè fi ri ojú rere Rẹ̀.

فوائد الحديث

Ìkìlọ̀ kuro nibi ẹbọ pẹlu gbogbo awọn ọna rẹ; ati pe o jẹ ìkọdí fún itẹwọgba iṣẹ ijọsin lọdọ Ọlọhun.

Níní ìmọ̀lára ọrọ̀ Ọlọhun ati titobi Rẹ̀, ó wà ninu awọn nkan tó máa n ṣe iranlọwọ lati jẹ ki a ṣe iṣẹ ní mimọ fun Ọlọhun.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah, Awọn iṣẹ ọkan