Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa

Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa

Lati ọdọ Salamah ọmọ Al-hakwa'u- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa", nnkan ko kọdi rẹ afi igberaga, o sọ pe: Ko si lee gbe e si ẹnu rẹ mọ.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ri arakunrin kan ti o n jẹun pẹlu ọwọ rẹ osi, o wa pa a láṣẹ lati jẹun pẹlu ọwọ rẹ ọtun, Arakunrin naa wa da a lohun ni ti igberaga ati irọ pe oun ko ni ikapa! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹbi le e pe ki wọn ṣe jijẹ pẹlu ọwọ ọtun leewọ fun un, Ọlọhun ba gba adura Anabi Rẹ pe ki ọwọ ọtun rẹ rọ, ko si lee gbe e si ẹnu rẹ lẹyin ìyẹn pẹlu oúnjẹ tabi nǹkan mimu.

فوائد الحديث

Jijẹ dandan jijẹun pẹlu ọwọ ọtun, ati jijẹ eewọ jijẹun pẹlu ọwọ osi.

Ṣíṣe igberaga nibi titẹle awọn ofin Sharia maa n mu ẹni ti o ba ṣe lẹtọọ si iya.

Apọnle Ọlọhun fun Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu gbigba adura rẹ.

Ṣíṣe pipaṣẹ pẹlu daadaa lofin ati kikọ kuro nibi ibajẹ ni gbogbo isẹsi koda nibi isẹsi jijẹ.

التصنيفات

Awọn ẹkọ jijẹ ati mimu, Awọn ẹkọ jijẹ ati mimu