Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu

Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu

Lati ọdọ Saheed ọmọ Al-Musayyab, láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ, o sọ pé: Nigba ti asiko iku Abu Taalib to, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ba a, o si ba Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah ọmọ Mughiirah ni ọdọ rẹ, ni o wa sọ pe: «Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu», ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Ṣe o fẹ gunri kuro nibi ilana Abdul Mutalibi ni, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si yẹ lẹni ti n fi lọ̀ ọ́ pe ki o wi i, ti awọn mejeeji naa si n paara ọrọ naa, titi ti Abu Taalib fi sọ nkan ti o ba wọn sọ gbẹyin pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ti o si kọ lati sọ: Laa illaha illā Allāhu, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mo fi Ọlọhun bura maa maa tọrọ aforijin fun ọ ti wọn o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ», ni Ọlọhun wa sọ ọ kalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ} [Al Taobah: 113]. Ni Ọlọhun tun wa sọ ọ kalẹ nipa Abu Taalib, ti O si sọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́﴿ [Al Qasas: 56].

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wọle tọ ọmọ-iya baba rẹ Abu Taalib ti o n pọka iku lọwọ, ni o wa sọ fun un pe: Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe "laa ilaaha illa Allāhu", gbolohun kan ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu, Ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Irẹ Abu Taalib, ṣe waa fi ilana baba rẹ Abdul Mutalibi silẹ ni? Oun si ni jijọsin fun awọn oriṣa, awọn mejeeji o si yẹ lẹni ti n ba a sọrọ titi ti o fi sọ ọrọ igbẹyin ti o ba wọn sọ pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ilana ẹbọ, ati jijọsin fun awọn oriṣa. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Maa ṣe adua aforijin fun ọ lopin igba ti Oluwa mi o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ, ni gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ba sọkalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n} [Al Taobah: 113], Ni o wa sọkalẹ nipa Abu Taalib gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe: ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà﴿ [Al Qaṣaṣ: 56], Dajudaju oo le fun ẹni ti o ba wu ẹ ni imọna, ati pe nkan ti o jẹ dandan fun ọ ni ki o jiṣẹ, ati pe Ọlọhun ni o máa n fi ẹni ti o ba wu U mọ ọna.

فوائد الحديث

Ṣiṣe wiwa aforijin fun awọn ọṣẹbọ ni eewọ bi o ti le wu ki isunmọ wọn ati iṣẹ wọn ati daadaa wọn o to.

Itẹle awọn baba ati awọn agbalagba lori ibajẹ ninu iṣe awọn alaimọkan ni.

Pipe aanu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ojukokoro rẹ lori pipe awọn eeyan ati fifi wọn mọna.

Esi fun ẹni ti o n lero Isilaamu Abu Taalib.

Awọn iṣẹ nibatise pẹlu awọn igbẹyin wọn (Ibiti eeyan ba pari iṣẹ si ni yio ṣe apejuwe ibiti eeyan maa de si).

Aidaa mimaa dirọ mọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ẹni ti o yatọ si i lati wa anfaani tabi lati fi ti aburu danu.

Ẹni ti o ba sọ "laa ilaaha illa Allāhu" ní ti imọ ati amọdaju ati adisọkan yio wọ inú Isilaamu.

Inira awọn ọrẹ buruku ati awọn alabaarin buruku lori ọmọnìyàn.

Itumọ "laa ilaaha illa Allāhu" ni: Gbigbe ijọsin fún àwọn òrìṣà ati awọn aayo ati awọn eniire jusilẹ, ati fifi ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati pe dajudaju awọn ọṣẹbọ naa mọ itumọ rẹ.

Ṣiṣe lẹtọọ bíbẹ alaisan ti o jẹ ọṣẹbọ wo nigba ti a ba n tanmọọn gbigba Isilaamu rẹ.

Imọna ìfiṣe kongẹ, ọwọ Ọlọhun nikan ni o wa ti ko si si akẹgbẹ fun Un, ati pe dajudaju eyi ti o jẹ dandan fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni imọna ijuwe ati itọsọna ati mimude ogongo.

التصنيفات

Alaye Kuraani, Ipepe soju ọna Ọlọhun