Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà rẹ̀ lọ, Iná naa sì rí bẹ́ẹ̀

Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà rẹ̀ lọ, Iná naa sì rí bẹ́ẹ̀

Lati ọdọ ọmọ Mas'ud - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà rẹ̀ lọ, Iná naa sì rí bẹ́ẹ̀".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fún wa niroo pé Alujanna ati Ina súnmọ́ ènìyàn gẹgẹ bi okùn bàtà tó máa n wà lókè ẹsẹ̀ ṣe súnmọ́, nitori pé ó ṣee ṣe kí eniyan ṣe iṣẹ ijọsin kan, kí iṣẹ yii sì mu un rí iyọnu Ọlọhun, yoo sì mu un wọ Alujanna, ó sì ṣee ṣe kó dá ẹṣẹ kan, kí ẹ̀ṣẹ̀ yii sì jẹ́ okunfa fun un tí yoo fi wọ Ina.

فوائد الحديث

Ìmúni nífẹ̀ẹ́ láti maa ṣe rere kódà bí ó bá kéré, ati ilenisa kuro nibi ṣiṣe aburu kódà bí ó bá kéré.

kò sí tabi-ṣugbọn fún musulumi nibi pé kí ó kó irankan ati ìbẹ̀rù papọ ninu aye rẹ̀, kí ó sì maa bẹ Ọlọhun Ọba ni gbogbo igba pé kí Ó mú oun duro sinsin lori ododo títí oun ó fi là, tí iṣesi tí oun wà ò fi nii kó itanjẹ bá oun.

التصنيفات

Awọn iroyin alujanna