إعدادات العرض
Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan
Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju larubawa oko kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan" O sọ pe: Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura mi ko nii lekun lori eyi, nigba ti o pa ẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹni ti o ba dun mọ ọn lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo eyi".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Kurdî Kiswahili Português සිංහල Svenska ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Tiếng Việt Hausa پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Malagasy नेपाली Čeština Oromoo Română Nederlands Soomaali తెలుగు മലയാളം ไทย Српски Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Lietuvių Shqip Wolof Українська Moore ქართული Magyarالشرح
Arakunrin kan ninu awọn ara oko wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati tọ ọ sọ́nà lori iṣẹ ti o maa mu u wọ alujanna, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe dajudaju wiwọ alujanna ati lila kuro nibi ina, méjèèjì duro lori pipe awọn origun Isilaamu, bii ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ki o maa gbe irun maraarun-un ti Ọlọhun ṣe wọn ni dandan lori awọn ẹru Rẹ duro ni gbogbo ọsan ati oru. Ki o maa yọ saka owo ti Ọlọhun ṣe ni dandan lori rẹ, ki o si fun ẹni ti o lẹtọọ si i. Ki o maa ṣọ awẹ Ramadan ni asiko rẹ. Arakunrin naa sọ pe mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura pe mi ko nii lekun nnkan kan lori iṣẹ ti a ṣe ni ọran-anyan ti mo gbọ́ lọdọ rẹ ninu awọn itẹle, mi ko si nii dinkun ninu rẹ. Nigba ti o pẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba dun mọ ọn ninu lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo larubawa oko yii.فوائد الحديث
Imu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni Ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin jẹ nnkan akọkọ ti èèyàn maa bẹ̀rẹ̀ pẹlu rẹ nibi ipepe si oju ọna Ọlọhun.
Gbigba tito pẹlu kikọ ẹni ti o ṣẹṣẹ gba Isilaamu ni àwọn ọranyan.
Ipepe lọ si oju ọna Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- dandan ni ki ṣiṣe e díẹ̀ díẹ̀ wa nibẹ.
Akolekan arakunrin naa lori wiwa imọ àlámọ̀rí ẹsin rẹ.
Ti Musulumi ba ṣe iṣẹ mọ lori awọn nnkan ti o jẹ dandan dajudaju o maa jere, ṣùgbọ́n eyi ko túmọ̀ si lilẹ pẹlu awọn nnkan aṣegbọrẹ; nitori pe aṣegbọrẹ wọn fi maa n pe adinku nibi awọn ọran-anyan ni.
Ṣíṣe ẹsa apakan ninu awọn ijọsin pẹlu didarukọ jẹ ẹri lori ijẹ pataki wọn ati isẹnilojukokoro lori wọn, ko túmọ̀ si aijẹ dandan awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn.
التصنيفات
Awọn ẹkọ olumọ ati akẹkọ