Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan

Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan, ati pe dajudaju ninu aṣehan ni ki ọmọnìyàn o ṣe iṣẹ kan ni oru, lẹyin naa ki o wa ji ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ, ki o wa sọ pe: Irẹ lagbaja, mo ṣe nkan bayii bayii ni alẹ ana, ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ ni alẹ, yio waa ji lati ṣi gaga aṣiri bibo Ọlọhun kuro».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Musulumi ẹlẹṣẹ ni o ṣeeṣe ki o ri amojukuro Ọlọhun ati aforijin Rẹ, ayaafi ẹni ti o ba n fi ẹṣẹ han ní ti ṣiṣe faari ati jijẹ aṣa, oun o lẹtọọ si amojukuro; latari pe yio da ẹṣẹ ni oru, lẹyin naa yio ji ni ẹni ti Ọlọhun ti bo aṣiri rẹ, ni yio ba sọ fun ẹlòmíràn pe oun da ẹṣẹ bayii ni ana, ti o si sun ti Oluwa rẹ ti bo o ni aṣiri, ni yio ba ji ti yoo waa tu aṣiri bibo Ọlọhun lori rẹ.

فوائد الحديث

Aidaa mimaa fi ẹṣẹ han lẹyin ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti bo aṣiri rẹ.

O n bẹ nibi imaa fi ẹṣẹ han titan ibajẹ ka laarin awọn Mumuni.

Ẹni ti Ọlọhun ba bo ni àṣírí ní aye yio bo o ni aṣiri ni ọjọ ikẹyin, ati pe eleyii wa ninu gbigbaaye ikẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu awọn ẹru Rẹ.

Ẹni ti wọn ba fi ẹṣẹ ṣe adanwo fun ki o bo ara rẹ ni àṣírí ki o si tuba lọ si ọdọ Ọlọhun.

Titobi ẹṣẹ awọn alaṣehan awọn ti wọn mọọmọ maa n fi ẹṣẹ han, ti wọn si maa n pa ara wọn ni adanu amojukuro.

التصنيفات

Aleebu awọn ẹṣẹ