Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ

Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe itọsọna lọ sibi ẹkọ sisalamọ laarin awọn eeyan "As salaamu alaykum wa rahmotuLloohi wabarakātuHu". Ọmọde o wa salamọ si agbalagba, ẹni ti o n gun nkan o si salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin o salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere o salamọ si awọn ti onka wọn pọ.

فوائد الحديث

Jijẹ sunnah sisalamọ lori bi hadīth naa ṣe gbe e wa, ti ẹni ti o n rin ba salamọ si ẹni ti o n gun nkan ati eyiti o yatọ si ìyẹn ninu nkan ti wọn sọ yẹn, o lẹtọọ, sugbọn ìyẹn yapa si eyi ti o fi n lọla julọ.

Titan salamọ ka lori ọna ti o gba wa ninu hadīth naa ninu awọn okunfa ifẹ ati asopọ lo wa.

Ti wọn ba ṣe deedee ara wọn ti wọn ba ara wọn dọgba nibi nkan ti wọn darukọ yẹn, nigba naa ẹni ti o loore julọ ninu wọn ni ẹni ti o ba kọkọ salamọ.

Pipe ofin yii nibi ṣiṣe alaye gbogbo nkan ti ọmọniyan bukaata si.

Ikọni ni awọn ẹkọ Isilaamu ati fifun oni iwọ ni iwọ rẹ.

التصنيفات

Awọn ẹkọ salamọ ati gbigba iyọnda