“Ti o ba jẹ pe ẹ n gbẹkẹle Ọlọhun gẹgẹ bi o ti yẹ ki ẹ gbẹkẹle E ni, Oun iba pese fun yin gẹ́gẹ́ bí O ti pese fun awọn ẹyẹ, ti wọn maa jade ni owurọ pẹlu ebi, ti wọn si maa pada ni irọlẹ ti wọn si ti yó.”

“Ti o ba jẹ pe ẹ n gbẹkẹle Ọlọhun gẹgẹ bi o ti yẹ ki ẹ gbẹkẹle E ni, Oun iba pese fun yin gẹ́gẹ́ bí O ti pese fun awọn ẹyẹ, ti wọn maa jade ni owurọ pẹlu ebi, ti wọn si maa pada ni irọlẹ ti wọn si ti yó.”

Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Oun gbọ ti Anọbi Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ti o ba jẹ pe ẹ n gbẹkẹle Ọlọhun gẹgẹ bi o ti yẹ ki ẹ gbẹkẹle E ni, Oun iba pese fun yin gẹ́gẹ́ bí O ti pese fun awọn ẹyẹ, ti wọn maa jade ni owurọ pẹlu ebi, ti wọn si maa pada ni irọlẹ ti wọn si ti yó.”

[O ni alaafia] [Ibnu Maajah ni o gba a wa]

الشرح

Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, gba wa niyanju lati gbẹkẹle Ọlọhun lati mu anfaani wa ati lati yago fun ipalara ninu ọ̀rọ̀ aye ati ẹsin. Ko si ẹni ti o le fun èèyàn ni nǹkan tabi fi nǹkan dun èèyàn, tabi ko inira ba èèyàn tabi ṣe èèyàn ni anfaani ayafi Ọlọhun Ọ̀gá-ògo, Ki a si ṣe awọn okunfa ti o maa mu anfaani wa, ti o si maa dènà ipalara, pẹlu gbigbẹkẹle Ọlọhun ti òdodo, ti a ba ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọhun maa pese fun wa bi O ti n pese fun awọn ẹyẹ ti wọn n jade ni owurọ pẹ̀lú ebi. Lẹ́yìn naa wọn maa pada ni irọlẹ ti ikun wọn si ti kún, ati pe iṣe ti ẹyẹ yii jẹ ọkan ninu awọn ọ̀nà igbiyanju lati wa jíjẹ-mímu, laisi igbẹkẹle asán ati ìmẹ́lẹ́.

فوائد الحديث

Ọlá ti n bẹ fun igbẹkẹle, ati pe o jẹ ọkan ninu awọn ọna ti o tobi julọ ti a fi maa n wa jijẹ-mimu.

Igbẹkẹle ko tako ṣiṣe awọn okùnfà; tori pe o sọ pe jíjáde ni owurọ ati pípadà ni irọlẹ lati wa jijẹ-mimu ko nii tako igbẹkẹle otitọ.

Akolekan Sharia si awọn iṣẹ ti awọn ọkan; tori pe ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ iṣẹ́ àtọkànwá.

Isomọ awọn okunfa nikan jẹ aipe ninu ẹsin, ti gbigbe awọn okunfa ju silẹ si jẹ aipe ni làákàyè.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ awọn ọkan, Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ awọn ọkan