“Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́”

“Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́”

Láti ọ̀dọ̀ Sahd ọmọ Abu Waqqaas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si awọn kan ninu awọn ẹru Rẹ, Ninu wọn ni olupaya: Ẹni ti n tẹle àṣẹ Ọlọhun, ti n jìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀. O tun nífẹ̀ẹ́ si ọlọrọ: Ẹni ti o rọrọ̀ pẹ̀lú Ọlọhun kuro lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, kii ṣíjú wo ẹlòmíràn. O tun nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ó pamọ́: Ẹni ti o ni ìtẹríba, ti maa n sin Oluwa rẹ, ti n kó airoju pẹ̀lú nǹkan ti yóò ṣe é ni anfaani, ti kii ni akolekan si ki ẹni kan kan mọ oun, tabi ki wọn maa yin oun.

فوائد الحديث

Àlàyé àwọn ìròyìn kan ti n beere fún ìfẹ́ Ọlọhun si awọn ẹru Rẹ, àwọn naa ni ipaya, ati ìtẹríba, ati iyọnu si nǹkan ti Ọlọhun pín.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin