Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”

Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii se ọlọ́rọ̀ burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ sọ ọrọ burúkú, o maa n sọ pe: “Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Ko si ninu ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o maa sọ̀rọ̀ buruku, tabi wu iwa burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e, o si jẹ oníwà ńlá. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ pe: Dajudaju ẹni tí ó ni ọlá jù ninu yin ni ọdọ Ọlọhun ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, pẹlu ṣíṣe dáadáa, ati ìtújúká, ati ki èèyàn ma fi suta kan ẹlòmíràn, ati fifi ara da suta lati ọdọ ẹlòmíràn, ati rírò pẹ̀lú àwọn èèyàn pẹ̀lú dáadáa.

فوائد الحديث

O di dandan fun onigbagbọ ododo ki o jìnnà si ọ̀rọ̀ burúkú àti ìṣe burúkú.

Pipe iwa ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii wa lati ọdọ rẹ ayafi iṣẹ rere ati ọ̀rọ̀ rere.

Ìwà rere jẹ pápá ìṣeré fun ìdíje, ẹni tí ó bá gba iwájú maa wa ninu awọn onigbagbọ òdodo ti wọn loore ju ti igbagbọ wọn si pe ju.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin