إعدادات العرض
“Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”
“Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”
Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands සිංහල தமிழ் دری Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy Română Kinyarwanda नेपाली Српски Wolof Soomaali Moore Українська Български Azərbaycan mr ქართული тоҷикӣ bm Oromoo Македонскиالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ ki a maa ka Kuraani nígbà gbogbo, ki a si maa tẹra mọ́ kika a ki èèyàn ma baa gbagbe rẹ lẹyin híhá a, o wa tẹnu mọ́ ọn pẹ̀lú ìbúra pe Kuraani yára kuro ninu àyà ju rakunmi ti a so lọ, oun naa ni eyi ti a fi okùn dè ni aarin ẹsẹ, ti eeyan ba n ka a nígbà gbogbo, o maa di i mu, ti o ba si tu u sílẹ̀, o maa lọ.فوائد الحديث
Ti ẹni tí ó ha Kuraani ba tẹra mọ kika rẹ léraléra o maa wa ni hiha ninu ọkan rẹ, bi bẹẹ kọ yoo lọ ti yoo si gbagbe rẹ.
Lara anfaani kika Kuraani nígbà gbogbo ni: Ẹ̀san, ati igbega ni ipò ni Ọjọ́ Àjíǹde.