Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba

Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba

Lati ọdọ Abu Al-Hayyaaj Al-Asadiy, o sọ pe: Aliy ọmọ Abu Tọọlib sọ fun mi pe: Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ran àwọn saabe rẹ pe ki wọn ma fi ère- oun ni aworan nǹkan ti o ni ẹmi ti o jẹ abara tabi eyi ti ko ni ara- kan kan sílẹ̀ afi ki wọn mu u kuro tabi ki wọn pa a rẹ. Ki wọn si ma fi sàréè ti o ga kan kan sílẹ̀ ayafi ki wọn jẹ ki o ba ilẹ̀ dọ́gba, ki wọn si wó nǹkan ti wọn kọ́ sori ẹ, tabi ki wọn ṣe e ni nǹkan ti o maa tẹ́ pẹrẹsẹ ti ko nii ga nílẹ̀ pupọ, ṣùgbọ́n o maa ga ni odiwọn àlààfo ti o wa laarin ìka àtàǹpàkò ati ika ọmọndinrin.

فوائد الحديث

Ṣíṣe yiya aworan nǹkan abẹ̀mí ni eewọ; tori pe o wa ninu awọn àtẹ̀gùn lọ síbi ẹbọ.

Mímú ohun buruku kuro pẹ̀lú ọwọ fun ẹni ti o ba ni àṣẹ tabi agbára lati ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ nǹkan ti o ba sharia mu.

Ojúkòkòrò Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori mimu gbogbo nǹkan ti o ba n tọka si oripa àsìkò aimọkan kúrò, bíi àwọn àwòrán ati awọn ère, ati awọn nǹkan ti wọn mọ sórí sàréè.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah