?Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un

?Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un

Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe dajudaju ẹni tí o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni alẹ, dajudaju Ọlọhun a to o kuro nibi aburu ati nkan ti ko dáa, wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi didide loru (irun oru), wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi awọn iranti yòókù, wọn tun sọ pe: Dajudaju mejeji ni odiwọn ti o kere ju ti o le to ninu kika Kuraani nibi idide oru (irun oru), wọn si tun sọ nkan ti o yatọ si ìyẹn, ati pe o sunmọ pe gbogbo nkan ti wọn sọ yẹn naa ni o daa ti gbolohun yẹn naa si ko o sinu.

فوائد الحديث

Alaye ọla ti o wa fun awọn aayah igbẹyin Sūratul Bakọra, ti o bẹrẹ lati ibi gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o wi pe: (Āmana rosūlu…) titi de ipari Sūrah naa.

Awọn igbẹyin Sūratul Bakọra maa n ti aidara ati aburu ati èṣù dànù fún ẹni tí o ba n ka a ti o ba ka a ni alẹ.

Oru bẹrẹ pẹlu wiwọ oorun, o si pari pẹlu yiyọ alufajari.

التصنيفات

Ọla ti n bẹ fun àwọn suura ati awọn aaya, Ọla ti n bẹ fun àwọn suura ati awọn aaya, Awọn iranti àárọ̀ ati irọlẹ, Awọn iranti àárọ̀ ati irọlẹ