“Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna

“Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna, ati pe itiju jẹ ipin kan ninu igbagbọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ jẹ awọn ipin kan ati awọn iwa ti wọn pọ, o ko awọn iṣẹ ati awọn adisọkan ati awọn ọrọ kan sinu. Ati pe eyi to ga julọ ninu iwa igbagbọ ti o si daa julọ nibẹ ni gbolohun: “Laa ilaaha illallohu”, ni mimọ ìtumọ̀ rẹ, ni ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o da le lori, bii pe dajudaju Ọlọhun ni Ọlọhun Ọba Ọkan ṣoṣo ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo yatọ si ẹni ti o yatọ si I. Ati pe eyi ti o kere julọ ninu awọn iṣẹ igbagbọ ni mimu gbogbo nnkan ti o le ko suta ba awọn eniyan kuro ni awọn oju ọna wọn. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju itiju wa ninu iwa igbagbọ, oun ni awọn iwa kan ti o maa n muni ṣe nǹkan daadaa, ti o si maa n muni gbé iwa buruku ju silẹ.

فوائد الحديث

Igbagbọ jẹ awọn ipo ti awọn kan lọla ju awọn kan lọ.

Igbagbọ jẹ ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan.

Itiju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa n beere fun: Ki Ó má ri ẹ níbi tí O kọ fun ẹ, ki O si ma wá ẹ tì nibi ti O pa ẹ láṣẹ.

Didarukọ onka ko túmọ̀ si pe orí rẹ̀ ni ó ti mọ, bi ko ṣe pe o n da lori pipọ awọn iṣẹ igbagbọ, nitori pe Larubawa le darukọ onka fun nnkan ti ko si nii gbero kikọ nnkan ti o yatọ si i.

التصنيفات

Lilekun igbagbọ ati adinku rẹ