Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”

Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”

Lati ọdọ Ibnu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ wọn maa ba wa wí nípa nnkan ti a ṣe ni asiko aimọkan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu, Ati pe dajudaju ẹni ti o ba gba Isilaamu ti Isilaamu rẹ si daa ti o si jẹ olumọkanga olododo; wọn ko nii ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ba ṣe ni asiko aimọkan ninu awọn ẹṣẹ, Ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu pẹ̀lú ki o jẹ ṣọbẹ-ṣelu tabi ki o ṣẹri pada kuro nibi ẹsin rẹ; wọn maa ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ṣe ninu aigbagbọ ati nnkan ti o ṣe ninu Isilaamu.

فوائد الحديث

Àkólékàn awọn Sọhaba- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- ati ipaya wọn ninu nnkan ti o n bẹ fun wọn ninu awọn iṣẹ ti wọn ṣe ni asiko aimọkan.

Isẹnilojukokoro lori iduroṣinṣin lori Isilaamu.

Ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu ati pe dajudaju o maa n pa awọn iṣẹ ìṣáájú rẹ́ ni.

Ẹni ti ko ṣe Isilaamu mọ ati ṣọbẹ- ṣelu, wọn yoo ṣe ìṣirò gbogbo iṣẹ́ kọọkan fun un eyi ti o ṣáájú ni asiko aimọkan, ati gbogbo ẹṣẹ kọọkan ti o ṣe ninu Isilaamu.

التصنيفات

Ẹsin Isilaamu, Lilekun igbagbọ ati adinku rẹ