Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ

Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọrọ nipa iwosan ti o ṣe anfaani fun awọn ibeere ti èṣù fi n ko royiroyi ba olugbagbọ, Èṣù o maa sọ pé: Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda sanmọ? Ta ni o ṣẹda ilẹ? Olugbagbọ yoo da a lohun ni ti ẹsin ati ti adamọ ati ti laakaye pẹlu ọrọ rẹ pé: Ọlọhun ni, Ṣùgbọ́n èṣù ko nii duro sibi aala yii ninu awọn royiroyi, bi ko ṣe pe yoo kúrò nibẹ titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Nibi ìyẹn ni olugbagbọ ti maa da awọn royiroyi yii padà pẹlu awọn alamọri mẹta kan: Nini igbagbọ ninu Ọlọhun. Wiwa isọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ èṣù. Kiko ara ro nibi titẹsiwaju pẹlu awọn royiroyi.

فوائد الحديث

Ṣiṣẹri kuro nibi royiroyi èṣù ati awọn èrò rẹ ti maa n wa si ẹmi, ati aironu nipa rẹ, ati sísádi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati mú u lọ.

Gbogbo nnkan ti o ṣẹlẹ̀ ninu ọkan ọmọniyan ninu awọn royiroyi ti wọn yapa ofin wọn wa lati ọdọ èṣù.

Kikọ kuro nibi ìrònú nipa paapaa Ọlọhun, ati ṣisẹnilojukokoro lori ìrònú nipa awọn ẹda Rẹ ati awọn ami Rẹ.

التصنيفات

Ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, Ẹsin Isilaamu, Awọn anfaani iranti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-