Ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ mi, ki o yaa lọ wa ibùjókòó rẹ ninu ina

Ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ mi, ki o yaa lọ wa ibùjókòó rẹ ninu ina

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ mi, ki o yaa lọ wa ibùjókòó rẹ ninu ina".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ ọn, pẹlu fifi ọrọ kan tabi iṣẹ kan ti si ọdọ rẹ ni ti irọ, dajudaju ibujokoo kan n bẹ fun un ni ọrun ninu ina; ki o maa jẹ ẹsan fun un lori pipa irọ mọ ọn.

فوائد الحديث

Irọ pipa mọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ti mimọọmọ jẹ okunfa wiwọ ina.

Pipa irọ mọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko da gẹgẹ bii irọ pipa mọ awọn eniyan yoku, fun nnkan ti o maa jẹ jáde latara ìyẹn ninu awọn ibajẹ ti wọn tobi ninu ẹsin ati ayé.

Ikilọ kuro nibi fifọn awọn hadiisi ka ṣíwájú ifirinlẹ ati amọdaju ninu nini alaafia ṣíṣe afiti rẹ sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

التصنيفات

Pàtàkì sunna ati ipò rẹ, Awọn iwa eebu