maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ

maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ

Lati ọdọ Abu Abdir-Rahmaan As-Sulamiy- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Awọn ti wọn maa n kọ́ wa bi a ṣe maa ka Kuraani ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wa pe àwọn maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ ti o wa ninu ẹ, wọn sọ pé: A wa kọ́ imọ ati iṣẹ.

[O daa] [Ahmad ni o gba a wa]

الشرح

Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu Kuraani, wọn ko si nii bọ si ibòmíràn titi ti wọn fi maa kọ́ imọ ti o wa ninu awọn aaya mẹ́wàá yii ti wọn si maa lò ó, o maa waa ja si pe wọn kọ imọ ati iṣẹ papọ nìyẹn.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ati ojúkòkòrò wọn lori kíkọ́ Kuraani.

Kíkọ́ Kuraani maa wáyé pẹ̀lú imọ ati lilo o, kii ṣe pẹ̀lú kika a ati hiha a nìkan.

Ìmọ̀ maa wáyé ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ.

التصنيفات

Imọ kika Kuraani dáadáa, Àwọn ẹ̀kọ́ kika Kuraani ati àwọn ti wọn ha a., Ọla ti n bẹ fun imọ