Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde

Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun àbúrò bàbá rẹ̀ pé: “Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde”, o sọ pe: Ti kii ba ṣe pe àwọn Quraysh maa bu mi ni, ti wọn maa sọ pé: Ìbẹ̀rù ni o mu un sọ ọ́, mi o ba fi dùn ọ́ nínú. Ni Ọlọhun wa sọ aaya yii kalẹ̀: {Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́} [Al-Qasas: 56].

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lati ọdọ aburo baba rẹ tii ṣe Abu Toolib ti o si n pọ́kàkà ikú lọ́wọ́- pe ki o pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, ki o fi le ṣìpẹ̀ fun un ni Ọjọ́ Àjíǹde, tí o si maa jẹrii fun un pe o gba Isilaamu, ó kọ̀ lati wí gbólóhùn ijẹrii naa ni ìpayà pe ki awọn Quraysh ma bu oun, ti wọn a maa sọ nipa oun pé: O gba Isilaamu tori ibẹru ikú ati ọ̀lẹ! O wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: Ti kii ba ṣe iyẹn ni, mi o ba dùn ọ́ nínú pẹ̀lú ki n wí gbólóhùn ijẹrii naa, mi o ba ṣe nǹkan ti o n fẹ́ titi ti wàá fi yọnu! Ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga wa sọ aaya kalẹ̀ ti n tọka si pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti kòńgẹ́ sinu Isilaamu, ṣùgbọ́n Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn nìkan ni O maa n fi ẹni tí Ó ba fẹ ṣe kongẹ. Ati pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fi ẹ̀dá mọ̀nà pẹlu itọka ati àlàyé ati ìtọ́sọ́nà ati ipepe lọ si ojú ọ̀nà tààrà.

فوائد الحديث

A kii fi òdodo silẹ ni ibẹru ohun ti àwọn èèyàn maa sọ.

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti itọka ati ìjúwe, ṣùgbọ́n ko ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti kòńgẹ́.

Abẹwo Kèfèrí ti o n ṣe aisan lati pe e sinu Isilaamu jẹ nǹkan ti o ba ofin sharia mu.

Ojúkòkòrò Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori ipepe lọ si ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo iṣesi.

التصنيفات

Nini igbagbọ si idajọ Ọlọhun ati ipebubu [Rẹ], Nini igbagbọ si idajọ Ọlọhun ati ipebubu [Rẹ], Ẹsin Isilaamu, Ẹsin Isilaamu, Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo