إعدادات العرض
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu
Lati ọdọ ọmọ Abu Aofaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu, Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”.
[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली తెలుగు Bosanski ಕನ್ನಡ Kurdî മലയാളം Oromoo Română Italiano Soomaali Shqip Српски Українська Wolof Moore Português Tagalog Malagasy தமிழ் Azərbaycan فارسی ქართული 中文 Magyarالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu ninu irun, o maa n sọ pe: “Sami’alloohu liman hamidaHu”, o n túmọ̀ si: Dajudaju ẹni ti o ba dupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa da a lohun, yio si gba ọpẹ rẹ ati ẹyin rẹ, yio si san lẹsan, lẹyin naa, o maa dupẹ fun Ọlọhun pẹlu sisọ pe: “Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”, ni ọpẹ kan ti o maa kun awọn sanmọ ati awọn ilẹ ati nnkan ti o n bẹ laaarin mejeeji, ti o si n kun nnkan ti Ọlọhun ba fẹ ninu nnkan kan.فوائد الحديث
Ṣíṣe alaye nnkan ti a fẹ fun olukirun lati maa sọ ti o ba gbe ori rẹ dide lati rukuu.
Ṣíṣe nínà tọ̀ọ̀ ati ifarabalẹ lofin lẹyin gbigbe ori kuro ni rukuu; nitori pe ko rọrun lati maa sọ iranti yii afi ti o ba nà tọ̀ọ̀ ti o si fi ara balẹ.
Wọn ṣe asikiri yii ni nǹkan ti o ba ṣẹria mu ninu gbogbo ìrun, bóyá o jẹ ọranyan ni tabi naafila.