إعدادات العرض
“Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?”
“Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?”
Lati ọdọ Abu Bakra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” O sọ bẹẹ ni igba mẹ́ta, wọn sọ pe: A fẹ bẹẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: “Mimu orogun pẹ̀lú Ọlọhun ati yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji”, o wa jokoo, o si jẹ ẹni ti o rọgbọku tẹlẹ, ni o wa sọ pe: “Ẹ gbọ o, ati ọrọ eke”, o sọ pe: Ko wa yẹ ni ẹni ti n wi i ni awitunwi titi ti a fi sọ pe: Iba tiẹ si dakẹ.
الترجمة
العربية Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Türkçe اردو 中文 हिन्दी বাংলা Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் සිංහල မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە ไทย دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली Malagasy Italiano ಕನ್ನಡ Oromoo Română Wolof Soomaali Српски Moore Українська Български Tagalogالشرح
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - n sọ fun awọn saabe rẹ nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nitori naa o darukọ àwọn mẹta yii: 1. Imu orogun pọ mọ Ọlọhun: Oun naa ni fifi iran kan ninu awọn iran ijọsin fun ẹlòmíràn yatọ si Ọlọhun, ati fifi ẹni ti o yatọ si Ọlọhun dọgba pẹlu Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ ati awọn iroyin Rẹ. 2. Yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji: Oun naa ni gbogbo ipalara ṣiṣe si obi mejeeji, yala ninu ọrọ tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn jù silẹ. 3. Ọrọ eke, ninu rẹ naa ni ẹri eke: Oun naa ni gbogbo ọrọ irọ ti wọn n fẹ lati fi tabuku ẹni ti o ba ṣẹlẹ si i, pẹlu gbígba dúkìá rẹ, tabi titayọ aala lori ọmọluabi rẹ tabi nkan ti o jọ bẹẹ. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti paara ikilọ kuro nibi ọrọ eke, lati ṣe itaniji lori ibajẹ rẹ (aidara rẹ) ati oripa aburu rẹ lori awujọ, titi ti awọn saabe fi sọ pe: Ko ba tiẹ si dakẹ; ni ti ìkáàánú rẹ, ati ikorira ohun ti o n yọ ọ lẹnu.فوائد الحديث
Ẹṣẹ ti o tobi julọ ni mimu orogun mọ Ọlọhun; nitori pé O ṣe e ni eyi ti o gba iwaju ti o si tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nkan ti o n fi idi eleyii mulẹ ni gbólóhùn Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe {Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.}.
Titobi awọn ẹtọ awọn obi mejeeji, latari pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga so ẹtọ wọn mọ ẹtọ ti Ẹ.
Awọn ẹṣẹ pin si awọn ẹṣẹ nla ati awọn ẹṣẹ kekere, ati pe awọn ẹṣẹ nla ni: Gbogbo ẹṣẹ ti o ni ijiya ni aye, gẹgẹ bii awọn ijiya to ni odiwọn ati ègún, tabi adehun iya ọjọ ikẹhin, gẹgẹ bii adehun iya pẹlu wiwọ ina, ati pe awọn ẹṣẹ ti o tobi ipele ipele ni, ti apakan rẹ si nipọn nibi ṣíṣe ni eewọ ju apakan lọ, ati pe awọn ẹṣẹ kekere ni awọn ti o yatọ si awọn ẹṣẹ nla.