Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri

Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri, ti ẹnikẹni ninu yin ba ji lati oju orun rẹ ki o yaa fọ ọwọ rẹ ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu omi aluwala rẹ, nitori pe ẹnikẹni ninu yin ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju". Ati ẹgbawa Muslim: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti ji lati oju orun rẹ, ki o ma ti ọwọ rẹ bọ inu igba titi yoo fi fọ ọ lẹẹmeta, nitori pe ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn idajọ imọra, ninu wọn ni: Akọkọ: Dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala, o jẹ dandan fun un lati fi omi si imu rẹ pẹlu èémí, lẹyin naa yoo mu u jade pẹlu eemi bakannaa. Ikeji: Ẹni ti o ba fẹ mọ ẹgbin ti o n jade lati ara rẹ, ti o fẹ mu u kuro pẹlu nnkan ti o yàtọ̀ si omi gẹgẹ bii okuta ati nnkan ti o jọ ọ, ki mimọra rẹ jẹ lori onka ti meji o le pin ti eyi ti o kere julọ nibẹ jẹ mẹta, ti eyi ti o pọ julọ nibẹ jẹ nnkan ti nnkan ti o n jade fi maa dá pẹlu rẹ ti aaye naa si fi maa mọ. Ikẹta ni: Ẹni ti o ba ji lati oju orun oru ko nii ti atẹlẹwọ rẹ bọ inu igba lati ṣe aluwala titi yoo fi fọ ọ lẹẹmẹta sita igba, nitori pe ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju, ko lee fọkanbalẹ nipa ẹgbin lori rẹ, Shaitan ti le ba a ṣere ti o le ti gbe awọn nnkan ti o le ko inira ba eniyan sibẹ tabi nnkan ti o le ba omi jẹ.

فوائد الحديث

Fifin omi si imu jẹ dandan nibi aluwala, oun ni: Mimu omi wọle sinu imu pẹlu ọna eemi, gẹgẹ bẹẹ naa ni fifin omi síta, oun ni: Mimu omi jade lati inu imu pẹlu ọna eemi.

Ṣíṣe mimọra pẹlu okuta ni nnkan ti a fẹ ni witiri.

Ṣíṣe fifọ ọwọ mejeeji lofin lẹyin orun oru lẹẹmẹta.

التصنيفات

Awọn ẹkọ bibiya bukaata, Aluwala, Awọn ẹkọ orun sisun ati jiji