Dajudaju ninu awọn eniyan ti o buru julọ ni ẹni ti ọjọ igbedide ba ba ti wọn si wa ni alààyè, ati ẹni ti o ba mu awọn saare ni mọsalasi

Dajudaju ninu awọn eniyan ti o buru julọ ni ẹni ti ọjọ igbedide ba ba ti wọn si wa ni alààyè, ati ẹni ti o ba mu awọn saare ni mọsalasi

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Dajudaju ninu awọn eniyan ti o buru julọ ni ẹni ti ọjọ igbedide ba ba ti wọn si wa ni alààyè, ati ẹni ti o ba mu awọn saare ni mọsalasi".

[O daa] [Ahmad ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ nipa awọn ti wọn buru julọ ninu awọn eniyan, awọn ni ẹni ti ọjọ igbedide to le wọn lori ti wọn si wa ni alààyè, ati awọn ti wọn maa n mu awọn saare ni awọn mọsalasi, ti wọn maa n kirun nibẹ ati si wọn lara.

فوائد الحديث

Ṣíṣe mimọ awọn mọsalasi lori awọn saare leewọ; nitori pe oju ọna lọ sibi ẹbọ ni.

Ṣíṣe kiki irun nibi saare leewọ, koda ki wọn ma mọ ọn; nitori pe mọsalasi jẹ orúkọ fun ibi ti wọn ba maa n forikanlẹ nibẹ, koda ki nǹkan ti wọn ba mọ ma wa lori rẹ.

Eni ti o ba mu awọn saare awọn ẹni rere ni awọn mọsalasi fun irun kiki nibẹ, o wa ninu awọn ti wọn buru julọ ninu awọn eniyan, koda ki o ro pe erongba rẹ ni wiwa asunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

التصنيفات

Àwọn àmì ti aye ba fẹ parẹ