Awọn alakatakiti ti parun

Awọn alakatakiti ti parun

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Mas'ud ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pé: "Awọn alakatakiti ti parun " ó sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo nipa ìpòfo ati ipadanu awọn onilekoko - laisi ìmọ̀nà ati ìmọ̀ - ninu ẹsin ati igbesi aye wọn, ati ninu awọn ọrọ wọn ati awọn iṣẹ wọn, awọn tí wọ́n máa ń tayọ aala ofin sharia tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mú wá fún wa.

فوائد الحديث

Eewọ ni ilekoko ati tipátipá ninu gbogbo nkan, kí a sì gbiyanju lati jina si mejeeji ninu ohun gbogbo; paapaa julọ ninu awọn ijọsin wa ati igbe-titobi fun awọn ẹnirere.

Wíwá lati ṣe ijọsin ati awọn ohun miiran ní pípé jẹ́ nkan dáadáa; ó sì ni lati jẹ́ pẹlu titẹle ofin sharia.

Wọ́n fẹ́ kí a maa tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ pataki, nitori pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tún gbolohun yii sọ ni ẹẹmẹta.

Ìrọ̀rùn ẹ̀sìn Islam ati àilekoko rẹ̀.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah