إعدادات العرض
“Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn
“Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe- An-Nuhmaan wa na ìka rẹ méjèèjì si etí rẹ méjèèjì-: “Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn, o wa n bẹ láàrin àwọn méjèèjì àwọn nǹkan ti wọn ruju, ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ko si mọ wọn, ẹni tí ó bá ṣọra fun awọn iruju naa, o ti wa mímọ́ fun ẹsin rẹ ati ọmọlúwàbí rẹ, ẹni tí o ba ko sinu àwọn ìríjú naa, yoo ko sinu nǹkan eewọ, o da gẹgẹ bii adaranjẹ̀ ti n da ẹran jẹ̀ ni etí ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò, o sunmọ ki o da ẹran wọ inu rẹ. Ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú gbogbo ọba ni o ni ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò. Ẹ tẹti ẹ gbọ, ilẹ Ọlọhun ti a da ààbò bò ni àwọn nǹkan ti O ṣe ni eewọ, ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú baaṣi ẹran kan n bẹ nínú ara, ti o ba ti dáa, gbogbo ara ti dáa, ti o ba si ti bajẹ, gbogbo ara ti bajẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ, oun naa ni ọkàn”.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands සිංහල தமிழ் ไทย دری Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek Moore नेपाली Oromoo Wolof Soomaali Български Українська Azərbaycan bm ქართული Lingala Македонскиالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé òfin kan ti o kárí nibi awọn nǹkan, o si pin si mẹta ninu ṣẹria: Ẹ̀tọ́ ti o fi ojú hàn, ati eewọ ti o fi ojú hàn, ati awọn alamọri kan ti wọn ruju ti idajọ wọn kò hàn nipa pe ṣe ẹtọ ni abi eewọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu awọn èèyàn ko mọ idajọ wọn. Ẹni ti o ba gbe àwọn nǹkan iruju yẹn jù silẹ, ẹsin rẹ maa ni àlàáfíà pẹ̀lú jíjìnnà sí kiko sinu nǹkan eewọ, ọmọlúwàbí rẹ naa si maa ni àlàáfíà kuro nibi ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn pẹ̀lú nǹkan ti wọn yoo fi maa bu u ti o ba ṣe nǹkan ìríjú yii. Ẹni ti ko ba jìnnà si awọn nǹkan ìríjú, ninu ki o ko sinu nǹkan eewọ, tabi ki àwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ọmọlúwàbí rẹ. Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àkàwé kan lélẹ̀ lati ṣàlàyé iṣesi ẹni tí o ba n ṣe àwọn nǹkan iruju pe o da gẹgẹ bii adaranjẹ ti n da ẹran rẹ jẹ ni tòsí ilẹ̀ kan ti ẹni tí ó ni i ti da aabo bo o, o sunmọ ki awọn ẹran rẹ jẹ ninu ilẹ̀ ti a da aabo bo yii torí wiwa wọn ni tòsí ibẹ, bẹ́ẹ̀ naa ni ẹni ti n ṣe nnkan ti ìríjú wa ninu ẹ, pẹ̀lú ìyẹn o ti n sunmọ nǹkan eewọ, o si sunmọ ki o ko sinu rẹ. Lẹyin rẹ ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé baaṣi ẹran kan n bẹ ninu ara (oun naa ni ọkàn), ara yoo maa dáa pẹ̀lú dídára rẹ, o si maa bajẹ pẹ̀lú bibajẹ rẹ.فوائد الحديث
Ṣiṣenilojukokoro lati gbé nǹkan iruju ju silẹ, eyi ti idajọ rẹ ko hàn.