إعدادات العرض
Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?
Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?" wọn sọ pe: Ko lee ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ, o sọ pe: "Gẹgẹ bẹẹ ni iru awọn irun maraarun-un, Ọlọhun maa n pa awọn àṣìṣe rẹ pẹlu rẹ".
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Kurdî Português සිංහල Svenska ગુજરાતી አማርኛ Tiếng Việt Hausa Kiswahili پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Malagasy नेपाली Čeština Oromoo Română Nederlands Soomaali తెలుగు മലയാളം ไทย Српски Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Lietuvių Wolofالشرح
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àwọn irun maraarun-un lojoojumọ nibi imukuro rẹ ati pipa awọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ ati awọn àṣìṣe, o fi we akeremọdo kan ti o wa ni ẹnu ọ̀nà ọmọniyan ti o n wẹ ninu rẹ lojoojumọ ni ẹẹmaraun-un, ti ko nii ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ ati ẹgbin rẹ.فوائد الحديث
Ọla yii jẹ ẹṣa fun pipa awọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ, sugbọn awọn ẹṣẹ nla, ironupiwada jẹ dandan nibẹ.
Ọla ti o n bẹ fun kiki irun maraarun-un ati sisọ wọn pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn dandan wọn ati awọn sunnah wọn.
التصنيفات
Ọla ti o n bẹ fun irun