Itiju wa ninu igbagbọ

Itiju wa ninu igbagbọ

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n ṣe wáàsí fun ọmọ-iya rẹ nipa ìtìjú, o wa sọ pé: “Itiju wa ninu igbagbọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n gba ọmọ-ìyá rẹ ni imọran pe ki o fi àpọ̀jù itiju silẹ! O wa ṣàlàyé fun un pe ìtìjú wa ninu ìgbàgbọ́, ko si lee mu nǹkan kan wa ayafi oore. Ìtìjú jẹ iwa kan ti o maa n mu èèyàn ṣe dáadáa, ti o si maa n mu èèyàn fi ohun buruku silẹ.

فوائد الحديث

Ohun ti o ba n ṣe idiwọ fun ẹ lati ṣe rere, a kii pe e ni ituju, ohun ti a maa n pe e ni ìdójútì, ati ikagara, ati ọ̀lẹ, ati ojo.

Ìtìjú Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn naa ni ki èèyàn maa ṣe ohun ti O pàṣẹ rẹ, ki èèyàn si fi àwọn nǹkan eewọ silẹ.

Ìtìjú ẹ̀dá naa ni ṣíṣe apọnle wọn, ki èèyàn si fi wọn si ipo wọn, ki èèyàn si jìnà si ohun ti o ba buru ni ti àṣà.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin