“Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”

“Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba sọ pe SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa ẹṣẹ rẹ rẹ, wọn si maa fi ori jin in, kódà ki ẹṣẹ rẹ pọ bii ifofo funfun ti o maa n wa lókè agbami odò nigba ti ìgbì rẹ ba n bì ati ti o ba ru sókè

فوائد الحديث

Ẹsan yii maa jẹ ti ẹni tí ó bá wí i ni ojúmọ́ léraléra tabi kélekèle.

AT-TESBIIH: Oun ni mimọ Ọlọhun kúrò nibi adinku, AL-HAMDU: Oun ni fifi pípé ròyìn rẹ pẹ̀lú ìfẹ́ ati gbigbetobi.

Ohun ti a gbèrò nibi hadiisi naa ni pipa àwọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ ńlá, dandan ni ki èèyàn tuuba kuro nibẹ.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun iranti