Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun

Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun

Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti mi, mo si ti bo apoti iko-nnkan-si ti o jẹ temi pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan n bẹ nibẹ, nigba ti o wa ri i, o fa a ya ti oju rẹ si pọn, o wa sọ pe: "Irẹ 'Aaisha, Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun" 'Aaisha sọ pe: "A si ge e, a si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- ninu ile rẹ, lo ba ri ti wọn ti bo apoti iko nnkan si kekere ti wọn gbe ẹru sinu rẹ pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan abẹmi n bẹ nibẹ, awọ oju rẹ si yipada ni ti ibinu nitori Ọlọhun, o si fa a ya, o wa sọ pe: Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun pẹlu awọn aworan wọn. 'Aaisha sọ pe: A si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì.

فوائد الحديث

Kikọ ibajẹ ni asiko riri rẹ ati aima lọra nibi ìyẹn, nigba ti ko ba si aburu nla ti o ju ìyẹn lọ nibẹ.

Iya ni ọjọ igbedide maa yatọ nibamu si titobi ẹṣẹ.

Yiya aworan awọn abẹmi wa ninu awọn ẹṣẹ ti wọn tobi julọ.

Ninu ọgbọ́n ti o n bẹ nibi ṣíṣe leewọ yiya aworan ni afijọ ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- boya oluyaworan gbero afijọ tabi ko gbero rẹ.

Ojúkòkòrò sharia lori sisọ awọn dukia pẹlu ṣíṣe anfaani latara rẹ lẹyin gbigbe e jina si nnkan ti wọn ṣe leewọ nibẹ.

Kikọ kuro nibi ṣíṣe awọn aworan abẹmi lori èyíkéyìí ìrísí ti o le jẹ, koda ki o jẹ ìyílẹ̀.

التصنيفات

Taohiid ti rubuubiyyah